irinkerindo ninu igbo elegbeje€¦ · irinkerindo se gbe kale. b. bawo ni irinkerindo se je si...
TRANSCRIPT
1
2
IRINKERINDO NINU IGBO ELEGBEJE
3
IRINKERINDO WOLE DE
1. Se iyato laarin oninakuna ati alahun gegebi
Irinkerindo se gbe kale.
b. Bawo ni Irinkerindo se je si Akara Ogun?
c. Kini oruko baba ati iya Akara Ogun?
d. Nibo ni Ilu Irinkerindo
2a. Kini eredi ti Irinkerindo ko fi tele Akara Ogun lo
si Oke Langbodo
b. Tani o so oro yii ati wipe tani o so oro naa fun
“Mase gbagbe ohun gbogbo ti mo ba o so wonyii,
iwo omo mi, ki Olorun ma atunrii bi Olodumare ko
ba ko atunri, a je pe ng o tun fi oju mi ri o, sugbon
iku ki ida ojo, beni kii da osu, eleda lomo ojo ati sun
eni. A ki mo bi o ba de ti o ba si gbo pe mo ti ku,
mase ba ara je, su osuka Pataki ki o gbe eru mi bi
okunrin.
4
c. Imoran wo ni Baba ati Iya Irinkerindo gba nigba ti
o fe rin irin ajo.
d. Tani o so oro yii?
“Irinkerindo, emi ni mo pe o. O ku inawo oku Baba
re, o ku asehinde, ki Olorun jeki ehin re dara. O ya
mi lenu bi Baba re ti se se be ku, nitori ni kete igbati
o fi ma ku, o wa si odo mi, ara re si le dada nigbana,
a tile soro ti o po, a fi igbati o si to ojo marun lehin
re, ti nwon mu ofo re wa ba mi – iku re na dun mi
lopolopo, nitori Oyindaiyepo ko je be lara mi, ki fii
oran mi sire, bi o ti wa ni ile re ni, ki ise ki o ma wa
be mi wo ni afin yii lekokan
3a. Iru ise wo ni Oba gbe fun Irinkerindo
b. Iru igi wo ni igi Ironu
c. Se apejuwe ibi ti Ibembe Olokunrun n gbe
d. Iru eniyan wo ni Ibembe Olokunrun je
5
4a. Tani o so oro yii ati wipe tani o un bawi
“Ni irinajo yii a o de ilu kan ni ibiti awon eranko
ngbe ti o je ilu won gan, ibiti iwo o ti ma ri to adota
agbonrin fun ounje aro, ogota imado fun ounje osan,
ati edegbefa kolokolo fun ounje ale.
6
IBERE IRINAJO SI OKE TI N ME NINU IGBO
ELEGBEJE
1a. Ni soki se apejuwe iru eda ti Kumodiran je
b. Tani oro yi n sapejuwe?
“O je arewa ena, o ga, o sigbonle, o si lagbara to be
ti nko iti gbo pe enikan fi ehin re bale ninu ijakadi re.
c. Se apejuwe eniti o n je inudimeji
d. Awon melo ni won yan lati lo si inu Igbo Elegbeje
e. Daruko awon eniyan naa.
2a. Ni oro kukuru se apejuwe awon eniyan wonyii:
i. Irinkerindo
ii. Aiyeduru eda
iii. Inulaiyewa
iv. Ewe Eye
v. Oloju Majele
vi. Kumodiran
7
vii. Filasaiyepo
viii. Ibembe-Olokunrun
ix. Ireke
b. Iyato wo lo wa laarin Igbo Irumale ati Igbo
Elegbeje
c. Tani o so oro yii
“Ara igbo, ero ona, e wa ba mi ra a o, o ja mi po,
owo kekere ni, warapa, poun meta, ori fifo, sile
mewa, soponna, poun meji, ete, poun merin, were
poun mefa, ese didun, sile mefa, inu rerun, sile
mewa, sobiya, poun kan, otutu, toro, lakuregbe,
pounkan abbl.
d. Se apejuwe iru eni ti inaki-gori-ite ati gongosu
takiti je
8
ALABAPADE ELEGBARA
1a. Tani Alujonu Elegbara
b. Tani nwon n ki bayii
“A ki iwoo, a ki iwo o, e yago fun u, e yago fun u, ma
roar, ma wole, kiyesi koto, kiyesi ipanti, kiyesi gelele
okuta.
c. Ko sile bi Irinkerindo se sapejuwe Elegbara
d. Tani Elegbara faya perepere?
9
ILU AWON EDIDARE NI IBITI
OMUGODIMEJI TI N SE OBA WON
1a. Se apejuwe bi Ilu awon Edidare se ri
b. Ko asa merin ti o wa ni Ilu Edidare
c. Sapejuwe bi Aafin Oba Omugodimeji se ri
d. Tani o so oro yii?
“Enyin alaimoye, eyin alaigbon, jijoko ti mo joko
nko joko ni ijoko oba ni, tabi abo ti mo woni ko to ti
Oba? Bi e ko mo nkan e ko mo iyi ibante mi? Bi oju
yin tile fo e o so pe e ko ri ade mii ni?Bi eko tile mo
gbogbo re eko ri afin mi ti o dara bi ilu mi? Enyin ti
e loju, e ko le fi reran. Bi e ko ba sora yin ng o ba yin
ja ki e kuro ni ilu mi.
2. Omugo dimeji, inu mi ko dun lati mo, o rara,
Didun bawo? Iwo omugo dimeji, eniti o pe o ni
omugodimeji kop e o bi o ti ye ki o pe o. Bi
omugo re ko ba rekoja meji, ile re a baje to bayii
10
loju ara re, iwo a tun maa ri enu soro? Iwo
alakori, yii ti o se ikun bi apo ekuro. Ibante wo lo
fi n se fari? – Ibante ni Oba nsan? Fila re gboro,
bi oju re ko ba fo, fila re ti iwo n pe ni Ade yi
dara ju Fila ori awa lo? O ni yi lo di odidi ojo
meje ti a ti n ranse se o pe ki o je ki a wa ri o,
gbogbo adehun ti o n ba wa se ni oun ye, sibe o
ko ronu ara re wo.
11
OMUGODIMETA GORI OYE, SOPONNA
GBE OMUGO DIMEJI LO
1a. Kini awon ara ilu Edidare se si Oku
Omugodimeji?
b. Tani o di Oba ilu Edidare lehin iku
Omugodimeji?
c. Bawo ni Ilaburu ati Danasungbo se je si
Omugodimeta
d. Eranko wo ni o dipo esin ni aafin ilu
omungodimeta.
2a. Ko igbagbo ounje eyi ti awon ara ilu nka te le
omugodimeta
b. Ki ni I de tin won fe fig be Omugodimeta re ile
ejo?
e.Ilu wo ni nwon ti n pe Oba lejo kobo kan
f. Tani o nje Apata-Igbehin.
12
EBORA IGBERAGA – IBANUJE ATI
AHONDIWURA IYAWO RE
“Eyi Okunrin de difa kan ti o fi ara jo Ade ti
onko monamona bi Okuta Diamondi, ewu re je
agbada nwon fi ge oniruru okuta Olowo iyebiye
pelebe, pelebe, nwon fi se ona sii lara, gbogbo
wonyii ndan gbinringbinrin bi igbati alagbede
Pataki ba se ohun oso didara fun gbajumo
obinrin ati sokoto, ati ewu, ati fila. Iwin yi ri
jingbinni kanle, bi o n ba si ti n rin, nwon ndun
jinwinjinwin bi igbati awon aborisa ba nlu ilu
agogo ijo orisa won. Eyi obirin dara to be ge, o
ro aso ileke were ko si iyato laarin Obinrin yi ati
awon omo araiye bi ko se ahon re ti o gun rekoja
ti o tayo enu ti o san si igba aiya re titi o fi kan a
ni dodo.
Tani oro yii n se apejuwe.
13
AFI OJU WA RI ORUN APADI
1a. Iru ebora wo ni Ebora Adeforiti?
b. Awon nkan wo ni o wa ninu Apoti ti Adeforiti
so nipa re
c. Ki ni Apoti naa duro fun?
d. Se apejuwe ohun ti Esu duro fun ninu itan naa.
2a. Bawo ni Esu se ri (gegebi won se sapejuwe
re)
b. Ibo ni o nje Pakute Esu?
c. Sapejuwe bi OrunApadi se ri?
14
WEREDIRAN TI NGBE ILE
OMUGOPARAPO
1a. Sapejuwe bi ilu awon alaseju se ri?
b. Iru eniyan wo ni Ogbeni Werediran?
c. Ki lo de ti awon ara ilu Alaseju fi maa n
sokun?
d. Ilu wo ni Werediran njo si?
2a. Ko sile bi awon onilu se nki Werediran pelu
ilu won
b. Ile wo ni oun je Wobia Parapo
c. Bawo ni Aiyedimeji se je si Werediran
15
ILU ITANJE ENIA
1a. Tani Agelebu Irinkerindo
b. Imoran wo ni aiyederu-eda gba Irinkerindo
nipa Iyawo re
c. Kilo fa ija laarin Irinkerindo ati Iyawo re
d. Tani o pa Oju aiyedun ati wipe iru iku wo ni
oku.
2a. Ki ni ohun ti Aiyederu-eda so pe ki won se
fun Irinkerindo
b. Ni soki, ko awon ijewo Aiyederu-eda
c. Ona wo ni o gba fi se Irinkerindo
d. Bawo ni Aiyederu eda se ku?
16
IGBEYAWO IRINKERINDO PELU ABURO
OLOGUN IWIN INU OMI
1a. So ni soki bi igbeyawo Irinkerindo pelu aburo
Ologun Iwin Inu Omi se lo.
17
18
ADIITU OLODUMARE
19
ADIITU OLODUMARE PADE IJANGBON LONA
NKAN SE
1a. Se apejuwe eni ti o ni ki Adiitu Eledumare lo be
Ogede wa ni oko.
b. Iru Oloye wo ni eni naa
c. Ki ni oruko Baba ati Iya Adiitu Eledumare
d. “O n ni yi, O n ni yi, On ni yi” ki lo fa oro yii ati wipe
tani oro yii nsapejuwe
2a.Iru awon ejo wo ni Anjonnu Ijongbon ro mon Adiitu
Eledumare lese fun awon igi.
b. Daruko awon oniruru eranko afayafa ti Anjonnu iberu
ko jade ninu apo re.
c. Ki ni Adiitu Olodumare ri ti o fi taji loju orun.
d. Tani o so oro yii ati tani o n so oro naa fun –
“Iroko, iwo ni awon omo enia nla se aga, iwo ni nwon
nla se ibusun, iwo ni nwon nla se apoti, iwo ni nwon tun
20
nfi se posi oku won. Ko si nkan ti nwon ko nfi oju re ri.
Wo eleyi, omo enia, o ko oniruru nkan buruku gbogbo, o
n gbe kiri lati ba fi se ibi. Eru buruku na lo wa lori re yi,
nje mo bi o, o ye ki n pa je tabi ko ye? O ye ki n pa eniti
ngbe ejo oka kiri lati fe se ibi tabi ko ye? O ye ki n pa
eniti ngbe paramole kiri fun ijamba tabi ko ye?
e. Ma bo, iwo ti o wa lori igi, ikun re bamba, ehin orun
re bakimo, ibadi re rapata yio se ipade ninu isasun obe
mi
Tani o so oro yii?
Ta si ni oro naa n bawi
3a. Daruko awon oye ti o wa ni Ilu Ifehinti
b. Ki ni o gbehin ekeji Oba ilu Ifehinti
c. Tania won Yoruba n pe ni abobaku ni ile Yoruba
d. Oruko miran wo ni a n pe abobaku ni ile Yoruba.
21
4a. Yato si ile Yoruba, orile ede miran wo ni a tun ti le ri
abobaku nigba lailai nile Afirika.
b. Nisisiyi o ti se ase-ma-se, o gbagbe ipo re o si ja sinu
kanga, o si omonikeji re lona, o fi oko oloko fun eni
eleni, Babalawo ilu dajo fun o, Olorise Ilu dajo iku fun
o, Sango ilu dajo iku fun o, Oya ilu dajo iku fun o,
Egungun ilu dajo iku fun o, Oro ilu dajo iku fun o, awon
Oso ati Aje, gbogbo Elebologun patapata, lomode,
lagbalagba, lokunrin, lobinrin ati gbogbo arugbo
porogodo, gbogbo won lo dajo iku fun o. Gegebi ofin
wa, ekeji ilu, ki ori re to kuro lorun re, wi fun ni, tani ki
o ku pelu re?
Tani o so eleyii?
Tani won so sii?
22
ALABAPADE ADIITU OLODUMARE
1a. Ni ojo ti mo ti nri ehin ti o funfun, nko ri ehin ti o
funfun bi ti okunrin naa ri, ni ojo ti mo ti nri ahon, nkori
eyiti o pon dede bi enipe onje ko da a ri bi tire, ni ojo ti
mo ti n ri oju ti o mole gara, nko ba iru ti okunrin yii
pade ri. Ki a si so pe enia soro o fi oro wu enileyi so,
enia rin lese, o fi irin wu elomiran rin, enia wo aso, o mu
ki a ma wo aso naa kiri, tabi iho ninu eni mo, tabi apa
eni ko gun lasan jawala, tabi omo ika owo ba owo mu,
omo ika ese ba ese mu, ti okunrin naa yato lopolopo.
Tani eniti n soro yii n sapejuwe?
2a. Igba ti ojo naa sip o pupo to bayii, dereba ko ri ibi
iwaju mo, asehinwa asehinbo dereba fa kokoro yo loju
moto, o gbe ese le ibi idaduro oko, oko duro gbonin, o di
ki a ma wa wo oju ara wa. Bi o si tile je pe ati gbogbo
ilekun mo ara wa lori pinpin, ti enikeni ko gbin, ti enia
ko soro, sibe okunrin kan lu moto le wa lori. Okan ilekun
lekini, o kan a lekeeji, o tun kan a lekeeta, a ba silekun a
wo ode”
23
Tani o n lu moto?
Ki ni oun lu moto si fun
24
OBIRI AYE ATI IPONJUDIRAN
1a. Ki enia ji, ki kobo se alai ba a ji, ki enia ko aso si ara
ki o dabi jowolo ogede fun akisa, ki odidi ile ojo kan su
lai bu omi si enu, ki enia di eniti o nti epo isu ti a fi gun
iyan je, ki enia bo si ori atan ki o ma wa epo buredi, ki
elewa je ewa tan ki a ma fi nkan ha redi ikoko ewa, ki o
di pe Oloye n wa onke a ti itori be lo le gongo sile
olonje, ki okunrin ni woro ibante kan gege bi aso, ki
obinrin ma ni ju yeri
Kini Olusoro nsapejuwe?
b. Durko oruko ilu Baba ati iya Adiitu Olodumare
c. So eredi ti awon ebi Adiitu Olodumare fi talaka to be
d. Se apejuwe eranko ti a n pe ni Ilakose?
e. Ki ni iyato ti o wa laarin igbin ati ilakose
2a. Ise wo ni awon ara ilu ilakose nse
b. Fi ami si ori awon oro wonyii:
25
i. Ilakose
ii. Gongosu
iii. Alainironu
iv. Bamubamu
v. Alaimero
vi. Obo Lagido
c. Tani o n kigbe bayii
E:- e:- e:- e- E- e- e- E jowo e gba mi o – o – o ! Gbogbo
ara aiye, egba mi, gbogbo ero orun, egba mi, gbogbo
anjonnu aiye, egba mi, gbogbo sigidi adahunse, e gba
mi, sango, jowo gba mi, Jesu onigbagbo, Obatala jowo
gbami, Anabi onimale, gba mi, Edumare, temi dowo re,
gbogbo omo ilakose, agbe ilakose, onisowo ilakose, eni
keni ni ilakose, e jowo e gba mio:-:-:-:-:-:-o”
26
ADIITU OLODUMARE DI ERO INU IGBO
1a. Baba mi, mo dupe lopolopo fun bibi ti e bi mi. Lai se
ainiaini, bi o ba je bayi ni e wa tele, e ko ba ti ni ero pe
ki e bi mi, e ko ba tile le to eniti nni obinrin. Sugbon
ayipada ti de. O di owuro ana ti mo ti fie nu mi ba onje
mo, sugbon nko ri ki enyin papa jeun, nko siri ki Iya mi
bu okele. Nitorina, mo fe lati jade kuro ni arin ilu, ki n fi
ori le ibikibi ti mo ba ri, boya bi emi ba lo, enyin ati iya
mi le ri ona ati ma toju ara yin, a je pe ng o ri yin,
sugbon bi eleda ba pe oni ni arimo, a o ma pade ni ode
orun.
Tani o soro yii
Tani oro naa n bawi
Kini esi ti eniti o n baa wi fo
b. Ko lessee ohun ti o sele si Adiitu Olodumare ni ojo
meta lehin ti o gbera kuro nile
c. Bawo ni Adiitu Olodumare se pa ejo buburu naa
d. Odun meelo ni Adiitu Olodumare gbe ninu Igbo
27
e. Kini iyato ti o wa laarin eniyan ati obo
2a. Ha! Eleda mi, temi ti je?
Olodumare, temi ti je?
Temi ti je laarin omo enia?
Baba mi wa onje, ko ri je
Iya mi wa onje ko ri je
Mo t’ori bo ‘gbo nitori ati je
Mo di egbe akata tori ati je
Alabagbe kiniun, tori ati je
Ekeji Imado tori ati je
Ona kona tin g o ba gba loni,
Iwo eleda mi, ma sai ko mi
i. Nje a le pea won oro oke yii lewi bi
ii. Tani o so oro yii
28
iii. Kini o sele ti o fi so awon oro wonyii.
b. Fi ami si ori awon oro wonyii
i. Teletele
ii. Sobolo
iii. Bamubamu
iv. Apoluku
v. Jowolo
vi. Ajedubule
vii. Edegbewa
viii. Akosile
ix. Obiri Aiye
x. Adiitu
c. Kini oruko omo itunu-aye aiyedemi
d. Awon nkan Ogun wo ni won pin kan lehin iku baba re
29
e. Awon nkan Ogun wo ni won pin kan Ireke Onibudo
funra ara re
2a. Se apejuwe iyato ti o wa laarin awon aso wonyii –
etu, alari, adire, aso elepa, sanyan, aso oke, damaasi,
aran.
b. Daruko awon nkan ti Adiitu Olodumare ra lo fun Iya
re
c. Iru iku wo ni o pa awon obi Adiitu Olodumare
d. Awon ohun wo ni Adiitu Olodumare se ni iranti awon
obi re
e. Awon ise ilu wo ni o tun se pelu.
30
ADIITU OLODUMARE LA ALA IYANU
1a. Ni soki se akosile ohun ti Adiitu Olodumare ri ni oju
orun
b. Ki ni ise angeli itoju emi?
c. Kini awon eran ohun osin ti won n wo tele ara won fe
lo se
d. Daruko awon eranko osin ohun
e. Ise wo ni digi n se ninu ala naa
2a. Iru ile wo ni ile Ope je
b. Iru awon eniyan wo lo n wo ibe
c. Salaye lekunrere itumo ati nkan ti awon wonyii duro
fun
i. Ako-okuta orun
ii. Akuko Orun
iii.Ogunlogo Apoti
31
d. Se apejuwe bi Akuko orun se ri
e. Ni soki, so ohun ti o sele laarin Adiitu Olodumare ati
Obiri-aiye
32
ADIITU NFE IYUNADE
1a. Bawo ni Ademe to se je si Adiity Olodumare
b. Kini a n pe ni Iyun ni ile Yoruba
c. Ise wo lo n se
d. Bawo ni Iyunade se je si Ademeto
e. Tani oro yii n se apejuwe –
“O dara lomobinrin, egan lo ku. O pupa roboto, gbogbo
ara ri minijo, ko sanra bakiti lasan, beni ko ru han-gogo,
o ri sosoro o sig a die, gbogbo nkan ti obinrin fi iwu ni
ni o ni gbogbo, eyinloju mole kedere, ko pupa rakorako
bi oju ejo. Bi enia ba wo ipenpeju re o dabi eni pe
Olodumare da tire se loto, ti o to nkan dudu tere sii, ete
ko fele rekoja, beni ko nipon pon-on-pon, ehin funfun bi
ojo ojo, ese ko ri tere bi ese oga, beni ko ri jakiti bi ti
ajanaku, ori ko ri gidigbi, kori palaba, kori gboro, eleda
se e ni iwon tunwonsi, o ba orun mu.
d. Kini esi leta akoko ti Iyunade kosi Adiitu
e. Daruko awon nkan ti Adiitu fi ranse si Iyunade
33
2a. Bi o ba fe fun mi ni nkan gege bi ore egbon mi, mo
gbo, bi o ba se mi ni alejo ti ko ni igberaga ninu, mo
gba, ki a wipe agolo atike kan pere lo ra wa fun mi, o ba
ri I bi o ti ma niyi to lowo mi, se ni mba gbe o soke ke-
nke.
Inu leta tani eyi ti je jade?
b. Kini o sele ti Iyunade fi n fi Adiitu Olodumare se yeye
c. Fi ami si ori awon oro yii
i. Gombu
ii. Yereku
iii. Ikoko
iv. Iyunade
v. Onibuore
vi. Onimale
d. Kini iyato ti o wa laarin omo buroka ati ipata omo
e. Kini o fa ti ara Iyunade ko fi ya
34
3a. Tani o so oro yii
Egbon mi, nko le be Adiitu rara, e jowo e je kin lo ola ti
Olodumare fun mi gegebi Obinrin. Lona kini Adiitu kii
se oko mi, ki itile se oko afesona rara, ki a wipe a fe ara
wa nijomiran ni mo le bee, sugbon eyi ni papa ko le bo
sii.
b. ki lo de ti Iyunade pe Adiitu ni Ogonju Orun
c. Tani esu-lehin ibeji
d. Kini o de ti esu lehin ibeji fe fi pa Adiitu
e. Tani esu lehin ibeji pa dipo Adiitu Olodumare
35
EHIN IGBEYAWO ADIITU OLODUMARE
1a. Tani Enudunjuyo
b. Tani o so oro yii
“Gbogbo eyin omo Ajedubule, mo ki yin, gbogbo alejo
Ajedubule, mo ki yin, mo ki onile, mo ki alejo, mo ki oso,
mo ki aje, mo ki babalawo, mo ki adahunse, mo ki
olowo, mo ki talaka, mo ki eniti o rije, mo ki eyiti ko rije
, gbogbo enyin igbagbo, mo ki yin, gbogbo enyin imale,
mo ki yin, gbogbo enyin aborisa mo ki gbogbo yin
porogodo.
c. Tani Oba Okonko
d. Kini Olori Esan-mbo se ti won fi ti mon inu iboji
e. Iru eniyan wo ni Alabapade je?
2a. Tani o gba ero lati pa Esan-mbo
b. Kini esi ti Esan mbo fun alabapade
c. Tani o n je omo owu
36
d. Ki ni alabapade ri lara esan-mbo nigba ti o fe sunmo
e. Tani o ko sibe
3a. Enu awon wo ni Oba ti gbo wipe Esan-mbo ko ku
b. Kini ase ti Oba Okonko pa fun awon onise re pe ki
won se fun Esa-mbo ati alabapade
c. Iru iya wo ni Oba Okonko fi je Esan-mbo
37
OJO KEJI NINU ILE MOGAJI ENUDUNJUYO
1a. Daruko awon eko ti a riko ninu itan Enudunjuyo
b. Iru eniyan wo ni Kotemilorun je
c. Ki ni oruko ore re
d. Iru awon Ibeere wo ni Esu Elegbara n bi awon ti won
wa si ipade
e. ki ni oruko ore Kotemilorun ti o bere lowo re wipe se
enia tun le lo si ibikan lehin iku?
38
39
OGBOJU ODE NINU IGBO IRUNMOLE
40
AKARA OGUN ATI AWON OBI RE
1a. Tani o so oro yii
“Mu ohun ikowe re, beresi iko itan ti emi o so wonyi sile,
mase fi I sile di ojo miran ki anfani re ki o ma ba re o
koja. Emi papa ki ba ti wa loni bikosepe mo nronu ehin
ola, nitori eru nba mi ki nmaba lo ku ni ai-rotele, ki itan
na si ku pelu mi, sugbon bi mo ba so o fun o loni, ti iwo
ba si ko o sile daradara, bi ojo mi ba tilw pe ti mo ku,
awon omo araiye ko ni gbagbe mi”.
b. Kini ise awon nkan wonyii ninu ise Ode sis
-Onde
- Ado
-Ato
c. Se apejuwe ni soki, iyato ti o wa laarin Igbe ode ati ise
agbe
d. Se alaye ni soki iku ti o pa Iya Akara Ogun
41
2a.Di awon alafo wonyii:
Beni mo ri ehin okunrin na sugbon nko gbodo yo jube lo
nitoripe nko mo ibiti mo wa rara. Ohun ti mo ko se lehin
ti mo pa a tan nip e mo wo inu iho re ni lo, nigbati mo
side inu re tan oniruru ohun alumoni aiye yi ni mo ba –
awon bi ileke, lagidigba ati awon aso bi
____________,__________,______________,________
_________ ati awon ___________ ti o gbe hau tin won
si lu ni olupopo. Motun ri oniruru fila awon bi
____________, ____________ ati ______________, mo
si ri ade meta ti a fi ileke se, bi Oba ba de won ko si eniti
o le ri oju Oba naa, ileke yio bo o loju.
b. “E maser o pe mo je tan yin je rara, mo fe ki e mo pe
ko si nkan ti mo gba lowo okunrin na lati ojo ti o ti so pe
on fe mi, se eniti o ba n ri mi lode yio ma ro pe on lo n se
nkan gbogbo fun mi! iro ni, bi o ti lowo to ni ko le fi
epinnin ba enikeni sire, opelope ejika ti ko jeki ewu k
obo. Opelope Iya mi ti ko jeki ebi yo mi loju je, bi ko ba
si ti iya mi emi iba si ma rin ni igboro ilu bayi, esinsin
iba ma kun mi, aja iba ti ma gbo mi. O lawun ju aja ti o
po onje sile tan ti o tun npada kooje. Bi esi ti n wo ni o
42
gbadun fari to nkan. Igbati o ba jaja lo si ilu onilu ti o
ba ri bi awon ayaba tin se tan a sese da a ma se kutakuta
ni on nfe ge aso fun mi; oloriburuku, olorunburuje afi bi
e pa a dandan. Ona pipa re na si ni yi – ko ju kekere lo –
bi o ba ti di oru oni ti gbogbo eniyan ba ti sun tan ngo
dide, ngo silekun afin sile, ki e yan awon akoni okunrin
merin ti awon ti ida ki won wole; iyara ti e ba ri ti ferese
re ba si sile ki e wo o, ibe ni Oba wa, enikeni ti e ba si ri
ni ibe ni oba wa. Enikeni ti e ba si ri nibe, pipa ni ki e
pa a?
-Kini ohun ti o mu iru oro yii wa
-Tani o so oro yii
-Awon wo ni ohun so oro naa fun
-Iru ete wo ni obinrin naa da.
43
IGBA EKINI AKARA OGUN NINU IGBO
IRUNMALE
1a. Ta ni oro yii n gbiyanju lati sapejuwe “Nigbati mo ti
wa ni bi omo odun mewa ni mo ti nba baba mi lo si igbe
ode, nigbati mo si ti to omo odun meedogun, ni mo ti da
ibon ni fun ara mi. Baba mi ku nigbati mo di omo odun
medogbon gere; nigbati o si ku yi, ati owo ti o ni ni ati
ogun ti o ni ni, ogun ni mo fi gbogbo won je ki o to ku
pelu, mo tin pa erin, owo mi si ti n ba efon, sasa eranko
ni ibon mi ko tile ti ipa.
b. Tani Olori-igbo
c. Olori-igbo!
Olori Igbo !
Iwo ni oloja Iwin
Mo ni iwo ni oloja iwin
Ko si Oloja to dabi re
Apa omo araiye ni iwo fin je iyan
44
Genge aiya won ni iwo fin je oka
Atari won ni iwo fin mu eko
Kini omo araiye maa fi o se!
Olori igbo o!
Iwo nfi ori rin ni n dan?
Mo ni iwo n fi ori rin ni ndan?
Nitori oju re n be ni idi re
O ntanna sese
Olori igbo o!
Are nse o ni dan?
Tabi etiri ti iwo ko le jade?
Gbogbo wa n reti re?
- Koko oro inu ewi yii ni
- Kini ise apetunpe oro n se ninu ewi yii
- Daruko marun ninu koseemani amuye ewi
apileko
45
- Ohun meji ti o se Pataki ninu ewi ni
- Sa awon ewa ede ati oro ijinle ninu ewi yii
2a. E:-:-:-:-:-:-e! ina ti mbe lodo ese, owo omo araiye ni
o. Niggati o wi bayi tan gbogbo won gbe oju soke; won
si ri mi. A! onijo njo, alayo nyo, nwon ndamuso nitori
mi, nwon nfe pa mi je. Ibiti now tin pa ero bi awon yio ti
se re mi lule ni mo ti ranti ogun mi kan bayii,
- Tani o nkigbe ina, ina, ina
- Tani won n wo lo’ke
- Kini eniti won n wo loke se lati le gba ara re la
b. Bayi ni enyin omo araiye ma n se, enyin
aforesunise, awa a ma wo yin, oju yin ko gbe ibikan,
e n ba hilahilo kiri, awon tin won ba ri je ninu yin,
nwon a ma wa ipo ola, nwon a fe ma jaiye oba, nwon
a gbagbe pe omo ika omo won ko dogba. Gegebi iwa
eda yin pelu, okan yin ki bale, eniti inu re ba dun
loni, awon eniyan re to ni simi lola; o ni iku, ola
arun, oni ija, ola airoju, oni ekun, ola ibanuje; ni
omo araiye ma n ba kiri, nigbati a wa ba si ronu
46
nipa tiyin, anu yin a se wa, awa a ma sokun nitori
yin, ikun a si ma yo ni imu wa, sugbo dipo ki eyina
wa fi eni wa tan wa, e ma fi ikun imu wa bu wa.
Tani o so oro yii
Tani oro naa n bawi
3a. Fi ami si ori awon oro wonyii
i. Igbo irunmale
ii. Merindinlogun
iii. Agbako
iv. Mariwo
v. Agiliti
vi. Kukute
vii. Edumare
viii. Hilahilo
47
xi. Tibinutibinu
x. Alailanu
48
AKARA OGUN ATI LAMORIN
1a. Tani ogboju Ode ba pade ninu Igbo Irunmale
b. Nibo lo ti mon
c. Tani o n je Ijanba
d. Oro wo ni Lamorin so nigba ti won foju kan
Lamorin
2a. Tani o so oro yii ati wipe tani oro naa nbawi
“E! ori mi, e! ori mi, awon kokoro sisanra yi logba;
‘E! ori mi, e! ori mi!
b. Tani o beere ibeere yii
“Nibo ni iwo ti wa nibo ni iwo sin lo? Eredi re ti iwo
fi n wadi mi?
Tani o fo esi yii
c. Fi ami si ori awon oro wonyii:
i. Lamorin
49
ii. Tembelekun
iii. Idarudapo
iv. Sarasara.
v. Ramumu
50
AWON ERO OKE LANGBODO
1a. Di alafo wonyii:
Iranse Oba kan lo dede wole ti o wi fun pe Oba n pe
mi. Eleyi ya mi lenu mo si dide mo wo ewu mi, mo de fila
________________ mo si wo sokoto____________mi,
mo mura o di ile Oba
b. Daruko awon Ogboju Ode ti won tele Akara Ogun
lo si Langbodo.
c. Tani o soro yii ati wipe tani o n ba wi
“Kini se to be o ko ni? Oran wo ni mo da tobe? Ese
wo ni mo se to be? Ona wo ni mo gba fi se yin? Eri
okunrin miran pelu mi ni? E gbo pe mo nsoro aidara si
yin ni? Mo nhu wa ole ni? Nko wa onje lakoko ni? Nko
fife han to ni? E gbo pe mo nja kakiri bi? E gbo pe oro
omo ita nti enu mi jedebi? Mo nna inakuna bi? Mo n se
aseju fari bi? Tabi mo nrin irin idoti ni ndan? Mo nhu
iwa aibikita si yin ni ndan? Nko gboransi yin lenu ni
ndan? Tabi nko tile mo ile itunse? Tabi nko mo alejo
itoju ni? Tabi nko mo ajo yin se to? Tabi nko ti le mo esi
51
oro ni? Tabi nko mo ajo yin se to? Tabi nko ran yin lowo
to ni ibi ise yin ni.
52
IGBA EKEJI AKARA OGUN NINU IGBO
IRUNMALE
1. Pin awon oro wonyii si Silebu, ki o si salaye ihun
okookan won
i. Omoluabi
ii. Losangangan
iii. Danindanin
vi. Tiyanutiyanu
v. Werewere
vi. Ehinkule
vii.Olorun buruja
viii.Epinni
x. Jagudapali
2a. Kini idahun eniti o ba soro
53
b. Nisoki so akitiyan awon ode wonyii ninu igbo
irunmale
- Akara Ogun
- Kako
- Imodoye
- Olohun Iyo
- Elegbe-Ode
- Efoiye
- Aramada-Okunrin
c. Tani o so oro yii:
“Enyin ara ilu wa gbogbo, e seun ti e wa lati wow a loni.
E hu iwa bi omo enia, e se bi omoluwabi si wa; e mu ki
ori way a, e mu ki aiya wa ba le, e mu ki okan wa si si
irin ajo wa. Bi ko ba si ohun ti o se ese, ese ki ise, bi ko
ba ni idi e ko ni dede se bayii ri wa. Gbogbo awa ti e n
woyii, Oke Langbodo ni a n lo, nitori ilu wa yin a si ni.
Ajo ki idun titi ki a ma ranti ile wa. Bi ilu eni kere ti o
54
dabi ite eiye, ilu eni ni ilu eni, ibi ilu eni re ehin ti oju
awon olugbe re ko la rara, ilu eni ni ilu eni, awon onilu
ni si ise ilu, awon ni iso ilu idoti di mimo, awon ni si iso
ilu kekere din la. Sugbon enikeni ti o ba wipe ilu on ki
idr t’on mo, gongosu enia ni.
3a. Ni oro kukuru, so iriri awon Ogboju ode ninu ilu
awon eiye
b. “Tani enyin wonyii? Nibo ni e ti wa? Nibo ni e si n
lo? Dajudaju ole ni yin, ami olosa mbe niwaju yin,
nitorina e se giri, ki Onibante san ibante; ki onisokoto
fun sokoto, ngo han yin lemo loni, ise meta ni e o se fun
mi, bi e ko ba si le se won, pipa ni ngo pa gbogbo yin je.
Tani o so oro yii?
c. Tani were-orun
d. Awon Ode Akoni melo ni won pa ni ilu awon eye.
e. Di alafo yii
55
_____________________ ki iwe; ewoni
_________________ oju re dabi ebi eniti o orun re dabi
ara opolo eri aiyebaiye si le moo, odudu bi ose ekolo,
ejo ati ________________ ni imi jade lenu re bi o ba n
soro, o n a si ma je won bi onje nigbati ebi ba de sii.
56
OJO EKEJI ATI OJO EKEJE LODO
IRAGBEJE NI ILU OLOJULEMEJE
1a.Ogboju ode melo ni won de odo iragbeje
b. Awon eko wo ni won riko lodo Iragbeje
c. Ni soki so itan kiniun ati awon eranko yooku
d. Se akosile eko ti itan na ko wa
e. Daruko awon eda ti o wa ninu itan na.
57
58
IREKE ONIBUDO
59
IGBESI AIYE MI NI ILU ALUPAYIDA
1. Bawo ni ife ti o wa laarin Ireke Onibudo ati
Ifepade se bere?
b. Se alaye lekunrere ohun ti o ri ko nipa ise ati ise
ilu Alupayida?
c. Tani o so oro yii
“Alakori ejo naa fe se ijamba ni, ko mo pe ojo
iku ti o n papa tip e.
2. Ni oro soki, se apejuwe ejo ti Ireke Onibudo pa
b. Tani o ko leta yi ati wipe tani won ko si:
“Ojo Kewa osu Kejila ni Edegbewa odun o le
Merindiladota Lehin Iku Oluwa wa,
Nko gbodo sai je ki e mo bi e ti je lokan mi, arin
okan mi ni e wa, ohun ti e se fun mi ko le se gbagbe
lailai, nko sile san a fun yin rara, eniti o ti itori eni
fie mi re wewu ti pari ore. Bi ko ba si enyin Ode
Orun ni akuko iba ko ba mi lojo oni – E ku itoju mi, e
jowo e ba mi fi owo ba onje kekere yii be ki e si ma
60
retie mi papa ni agogo merin ola. Baba ki yin, Iya mi
si ki yin pelu.
d. Akuko iba ko ba mi lojo oni tunmo si?
3. Tani o so oro yii ati tani won so oro naa si!
“Mo ro pe o to akoko ki n wa soro fun o. O to
akoko o to ge, o wa gegebi bi alainitiju enia,
Olodumare si wa laarin temi tire. Kini enyin
obinrin mo nipa okunrin ju pe ki e duro bi apata
lehin re igbadun, ki e sa bi igbati omo eran bas a
fun yin, ki e ma lo ola kii e si ma yo ninu aso
olowo iyebiye, ki e ma pe pelu awon enia Pataki,
sugbon e dabi ejo oloro labe koriko, paramole ti
n bu enia lese je, eniti n da ija sile ti o n ta kete.
Bayii ni e je eyin obinrin. Sugbon iwo, kini
alakori re gbekele? Se baba re yii naa ni, kini ati
iwo ati baba re jamo? Kini eniyan nfe lara iwo
papa? Iwo jagbajagba, rederede, randanrandan,
galagala, jagajaga, yagbayagba, o wa o ko ni
ero lori rara, ko si ibi ti o ko le de, boya o tun ti
ba okunrin miran lo ni, ki iwo ati baba re ma se
61
bi e ba ti fe, bi iwo papa tile tun mi n ko fe o mo,
mo lo fun o ati fun oloriburuku re na o.
b. Se alaye awon oro wonyii
i. Ejo oloro labe koriko
ii. Paramole ti n bu enia lese je
c. Fi ami si ori awon oro wonyii:
i. Jagbajagba ii. Rederede iii. Randanrandan
vi. Galagala vii. Jagajaga viii. Yagbayagba
62
ALABAPADE IREKE-ONIBUDO
1a. Tani omo Akintunde ti ise omo Beyioku?
b. Awon Alaru meelo ni won tele alejo Ireke Onibudo?
c. Awon oro wo ni Ireke Onibudo ati alejo re jo so?
d. “A soro nipa irawo wonni, a ronu bi ogbon
Olodumare ti to, bi ojo ojo ro, ko ro ina ti olodumare tan
si oju orun ki iku, eleda kii iwa epo atupa kaakiri, ile
onile, atupa Olodumare ki ifo, epo atupa re kii itan, kii
isi danu, beni afefe ko lagbara loriina ti olodumare tan
si oju orun.
Oro wo lo fa awon oro wonyii?
e. Wo mi dada, wo mi ki o tun mi wo, wo mi ki o baa mo
eni ti emi n se. Moti rekoja omi okun ti o yii aiye po, mo
ti rekoja omi osa ti o wa ni opolopo orile ede, mo ti de
aginju nibiti igbo dudu minrinmirin, mo si ti de aarin
awon kiniun ati amotekun, ikoko ati imado, ekun ati
agbalangbo, oka ati ere, lekeleke ati adan, Iroko ati
Oganwo, ati ologo se ti iru re ri gboro.
63
Tani o so awon oro wonyii?
2a. Omo odo a maa gbon ju Oluwa re? Bakanna ni pelu,
awon elomiran a wa ni ibi ise, oga won a fi iya je won
sugbon dipo kin won roar ma ba ise won lo ni ti won
awon n wa orun ki nwon a ni awon n wa Ifarapa oga
awon, awon were, awon dangisola gbogbo dipo kin won
roju kin won fi ara da isoro titi awon naa a fi di oga fun
awon elomiran nwon a ma se ileri ohun ti awon o se.
Nwon ti gbagbe pe ki enia to le ri anfaani nla olwa re ni
lati jiya nla, ki enia to le de ipo nla Oluwa re ni lati mu
suru nla, omo odo ko le gbonju oluwa re lo.
Ni oro tire ni soki, se itupale oro imoran yii?
b. Mo si tun fe ki o mo pe elomiran wa tin won duro
gegebi egun osusu ati atelese si arin awon omo enia
awon ti eri okan won ti ku ti o je pe Olodumare ni o mo
ona ti won le fi ji eri okan won dide, bi iru awon mon nib
a se o ni ibi kan se ni ki o yara maa sa lo, nitori bi o ba
wipe o fe gbesan nwon o se o ni meji, bi o ba duro n won
o se o ju meji lo ati papa, awon wonii ti mo ona ibi tobe
64
ti o fi je wipe ati mu won soro gidigidi. Bi enia kan ba fe
oniwa lile, ti o nse ipanle kiri, mase fi ara we e lailai,
nitori bi iwa ipanle ko ba si ni eda re, ekansoso ti iwo ba
se tire ni owo awon alagbara yio te o tin won yi fi iya je
o dada.
i. Se afiwe imoran yii pelu eyi ti o wa loke?
ii. Awon eko wo ni imoran yii ko wa?
c. Se apejuwe ati iyato ti o wa laarin awon eranko wonyii
i. Kiniun ati amotekun
ii. Ikoko ati Imado
iii. Ekun ati Agbalangbo
vi. Oka ati Ere
vi. Lekeleke ati adan
vii. Iroko ati Oganwo
d. Ni ede tire, ni kukuru, so itan Olongbo Ijakadi ati
Ekun
65
e. Eko wo ni itan Olongbo Ijakadi ati Ekun ko wa.
2a. Daruko awon nkan eto ti Olongbo Ijakadi fe fi se
Ogun-ikola fun awon omo ekun
b. Ninu itan Olongbo Ijakadi ati Ekun, Eranko wo lo so
eyi “ Ore mi Pataki, ore mi o to, ore mi gan, ore mi
ododo, ore mi atata, ore mi pato, ore mi owuro, ore mi
osan, ore mi ale, ore mi aiye, ore mi orun, ore mi lati ori
de gongo imu, ore mi lati orun de atelese, ore ti o ju iya,
ore ti o ju irekan, ore ti o ju obirin eni lo-
c. Se apejuwe iru eranko ti Olongbo Ijakadi n se.
d. Se alaye lekunrere awon ibi ti o ja lu ekun
Awon eda itan meelo ni won wa ni inu itan Olongbo
Ijakadi ati ekun
3a. Orisirisi gbolohun meelo ni o suyo ninu itan Olongbo
Ijakadi ati ekun
66
b. Fi awon eka gbolohun wonyii se apeere
i. Gbolohun Alaye
ii. Gbolohun Ase
iii. Gbolohun Ibeere
vi. Gbolohun Apejuwe
vii. Gbolohun Akiyesi
c. Se Ogbufo awon oro wonyii
i. Se Ogbufo awon oro wonyii
i. Igbonwo
ii. Imado
iii. Agbalangbo
vi. Ogan wo
v. Olojose
vi. Alarekereke
vii. Otelelegbeje
67
viii. Rogbodiyan
ix. Arin Oganjo
x. Alailanu
d. Tani o so oro yii:
“Ore mi ti mbe loke odo, o ku rogbodiyan na, se ko si
nkan ti iyawo re fi n yi ni ile gbiri? Jowo lo si isale yio
yii bo si inu omi. Mo tile fe so kini kan fun o, eran awon
omo re ma tile dun o, akobi re ni o le die, sugbon
sibesibe na mo fo o de ile koko, eran abikehin re ni mo
gbadun ju, egungun re roar nrun si mi lenu ni, nko si ni
gbagbe agbari omo naa lailai, mo fi ehin fo o dada. O
digba die naa, lojo tie bi ba n pa mi ng o wa ye ile re wo,
bi o ko ba si ti ibi omo miran dajudaju n o ri paje ninu
awon ibatan re, o digba o.
68
PIPADE AWON ABAMI EDA
i. So ni kukuru itumo ahere
b. Se apejuwe bi ahere aye atijo se maa n ri?
c. Daruko ohun meji ti o yepere ni oju awon agbe
d. Daruko nkan abami meje eyi ti Eledumare da sinu oko
lati le fi agbara re han.
e. Ki ni oruko obirin ti won bi tele Ireke Onibudo
2a. Ko ga ju ibadi mi lo je gbolohun
___________________________
b. Se alaye lori
i. Ara re dabi aseseyo eweko
ii. Ehin re funfun bi oju orun
iii. O wo ewu funfun nini
c. Se apejuwe awon oro wonyii
69
i. Eyin ni n di akuko
ii. Igba ewe ni n fi igba igba han
iii. Gongbo ni Pataki lara igi
iv. Orisun omi ni ise alakoso omi
d. Se alaye lessee awon imoran ti abami eda gba Ifepade
e. Se agbekale awon oro wonyii gegebi o ti ye o:
i. Ara awon ohun ogbin tutu nini
ii. Isu ti lo mo eya isu ti bo ruru
iii. Ewa ila ri gberegede gberegede
iv. Efo tete ri gbogagboga
v. Ogunmo ri gbegegbege
vi. Elegede yo owo sarasara
vii. Ewe osunri gbaragada Gbaragada
viii. Oyo dudu mirinmirin
ix. Akengbe fa bo ile
70
3a. Wa oro miran ti o ni itunmo oro wonyii
i. Ebiti
ii. Takute naa ti ru
b. Se alaye ni soki, bi Ifepade se sapejuwe Abami Eda
naa
c. Se Ogbufo awon oro yii si eda Oyinbo
i. Digi
ii. Kukute
iii. Yanrin
Iv. Rugudu
v. Apamowo
vi. Alakoso
vii. Digbose
viii. Apo Owo
ix. Awojiji
71
x. Bikita
xi. Ogunlogo
xii. Bulabula
xiii. Arekereke Okunrin
xi v. Rikisi
vx. Gboyisoyi
d.Kini ibeere ti Abami eda bi Ireke Onibudo
e. Se alaye ohun ti Ifepade ri leti odo ti Abami Eda naa
mu lo
4a. Ko itumo owe yii
I. Ori awuje ni awuje fi igbe ile jade, ori okiti ogan ni
okiti ogan njinle
b. Se alaye ni soki lori orisirisi asa Yoruba ti o ba pade
ninu apa kini yii
72
c. Awon igbadun wo lo ri fayo ninu awon itan inu eko
yii?
d. E meelo ni abami eda yii si Ireke Onibudo loju orun
e. Wa apeere awon owe merin ninu itan ti a ka tan yii ti o
je mo
a. Imoran b. Ikilo c. Alaye d. Ibawi
73
OJO KEJI ALABAPADE IREKE ONIBUDO
a. Tete parada, tete parada, ore mi, ojo nlo
i. Tani o soro yii
ii. Ta ni nwon soro sii
b. Tani oruko re n je Adeorun?
c. Tani o so oro yii
“ Iwo omo mi, Ireke-Onibudo, bi mo ti now oro mi yii,
nko ro pe mo le yo ninu aisan yii, beni nko ni nkankan
sile fun o. Mo fi o le Olodumare lowo, bi mo ba ti ku tan,
se ni ki o jade ni ilu ki o maa lo si ibikibi ti o ba ri. Baba
re tit a gbogbo nkan ti mo ni ki o to ku o si fi mi sile ni
ihoho ni ode aiye, bayii ni aiye mi ba je loju mi, nko se
enikeni ni ibi re, nko si hu iwa ika si omonikeji
2a. Pelu apeere to tona, se alaaye orisirisi osunwon ti a fi
n da silebu mo ninu ede Yoruba.
74
b. Pin awon oro wonyii se sileebu, ki o si salaye ihun
okookan won.
i. Omoluwabi
ii. Adeorun
iii. Ireke Onibudo
iv. Mejilelogbon
v. Olodumare
vi. Oluigbo
vii. Afowobafisile
viii. Nhanrun
c. Se ogbufo awon oro wonyii:
i. Nhanrun
ii. Aimoye
iii. Odunrun
vi. Afowobafisile
75
v. Tembelekun
3a. Tani o so oro yii
“Omokunrin se ni ki o wa ibis a pamo si nigbati o ba di
oju ale nitori nwon le bo sokoto idi re lo
b. Se apejuwe ilu ero-ehin ati ogbeni Rikisi-gori-ite
c. Koa won ofin ti awon ara ilu ero-ehin gbodo maa tele
lojojumo
76
ITANFORITI TI NGBE INU IHO ILE
1a. Se apejuwe iru eda ti Itanforiti ti ngbe inu iho ile je
b. Daruko mejo ninu awon imoran ti o gba Ireke
Onibudo
c. Tani oriki re n je Alagidi-okunrin
2a. Kini oruko oke ti Ireke onibudo ati ore re gun koja
b. Daruko ida maarun ninu itan yii
c. Fi ami si ori awon oro wonyii:
i. Hilahilo
ii.Anjonnu
iii. Itanforiti
iv. Kumofehinti
v. Ero-ehin
vi. Ihoho
77
vii. Gbaiyegborun
viii. Irewesi
ix. Ijangbon
x. Odomobinrin
3a. Tani o so oro yii ati wipe tani o n ba wi?
“ Enyin omo enia, bakanna ni e je oniruru ni ode aiye,
eleda ko pin ebun ti o fun olukuluku dogba. Elomiran wa
o ni ebun oro siso, bi o ba soro bi enipe ki won maa pon
enu re la ni. Elo miran wa ti ko le soro pupo sugbon ti o
le ronu ju elomiran lo, le soro pupo sugbon ti o le ronu
ju elomiran lo, elomiran je arewa ti o n wu gbogbo eda
alaye; omiran je aburewa, ti ko fa enikeni mora;
elomiran ga fiofio, omiran kuru o dabi kukute; omiran si
mo ni iwontunwonsi, bi o ti wu eleda ni o pin ebun re
laarin awon omo araiye.
ii. Pin awon oro wonyii si silebu ki o si salaye ihun
okookan won?
78
i. Hilahilo
ii. Itanforiti
iii. Kumofehinti
iv. Ero-ehin
v. Ihoho
vi. Irewesi
vii. Ijangbon
viii. Odomobinrin
c. Ko awon owe inu itan naa jade.
4a. Pin awon oro wonyii si silebu ki o si salaye ihun
okookan won
i. Tagbaratagbara
ii. Itakun
iii. Lofurufu
iv. Apanirun
79
v. Iwontunwonsi
vi. Wundia
vii. Arogidigba
viii. Diamondi
ix. Winnikin
x. Pepeiye
80
AROGIDIGBA TI ISE OLORI EJA INU OMI
1a. Eyiti o ya mi lenu ju gbogbo re lo ni pe bi oko wa ti
da ojude ti mo n gbiyanju ati di igi re mu ni enikan nfa
mi ni ses ni isale. Nigbati o pe ti mo ti n ja o re mi mo si
fi ara mi sile fun iku. Sugbon nigbati mo de inu omi
lohun ni mo ri eniti nfa mi naa, o gbe apoti digi n la kan
lowo o si ti mi si inu apoti naa, on naa yo mo nmi dada
mo sir ii pe ki ise enia ni okunrin ti o mu mi si inu apoti
na, o san ibante, ko ni irun lori, ekan owore si gun
sobolo, o ni iru ni idi to bi ju ti enia lo o si ri roboto bi
osupa. O ni irun gigun sanransaran, ni inu ti o fi ara we
eja, ehin re dabbi ti kiniun, o tobi o si nipon.
Tani oro yii n se apejuwe?
b. Fi ami si ori awon oro wonyii
i. Sobolo
ii. Sanransanran
iii. Digi
iv. Deruba
81
v. Felefele
vi. Ikarawun
vii. Roboto
viii. Mirinmirin
ix. Winnikin
x. Rederede
c. Salaye soki lori orisirisi asa Yoruba ti o ba pade ninu
itan Arogidigba ti ise olori eja inu omi
2a. Tani o so oro yii
- Mu u duro, mu u duro lohun ni, omo enia ko
gbodo de sakani mi, kini omo enia je? O je akeke
ti o wa fun ipalara, paramole labe koriko, eni
ibanuje fun awon eda alaye, enia duro bi eniti o
fi oju ida re bo ile, o nlo ola ti Olodumare fi fun u
rederede. Tani to yin, enyin enia? Ki si ni ilo tin
si awon eja?
b. Se ogbufo awon oro wonyii:
82
i. Koriko
ii. Agbegbe
iii. Akeke
iv. Felefele
v. Perese
vi. Akengbe
vii. Ikoko
viii. Adahunse
ix. Tagbaratagbara
x. Pepeiye
c. Se apejuwe awon ise kanrinkanrin ti Arogidigba ti ise
Olori Eja inu omi gbe fun Ireke Onibudo
3a. Salaye lekunrere ohun ti o sele ninu oro yii “Bi o ti n
jab o ni orun mu, were o fi omobirin yii sile, o koju simi
o fi ori so mi nigba aiya mo si tit a gebe losiwaju,
83
lehinna ejo buruku yii lo mi ni idi o si ka we milara lati
idi mi de orun, lehin eyi o n fi iru re na mi, o na mi debi
ti mo fisubu tie mi ati oun nyi lo gbirigbiri.